Orin 237
‘Bugbe Rẹ ti l’ẹwa to!
Pleasant are thy courts above
- f ‘Bugbe Rẹ ti l’ẹwa to!
N’ ilẹ ‘mọlẹ at’ ifẹ;
Bugbe Re ti l’ẹwa to!
Laiye ẹṣẹ ati’ òṣì,
Ọkan mi nfà nitotọ
Fun idapọ̀ enia Rẹ,
Fun imọlẹ oju Rẹ,
Fun ẹ̀kún Rẹ, Ọlọrun. - f Ayọ̀ ba awọn ẹiyẹ,
Ti nfò yi pẹpẹ Rẹ ka;
Ayọ̀ ọkàn t’o simi
L’aiya Baba l’o pọju!
Gẹgẹ b’adaba Noa,
Ti ko r’ibi simi le,
Nwọn pada sọdọ Baba,
Nwọn sì nyọ̀ titi aiye. - f Nwọn kò simi iyìn wọn,
Ninu aiye oṣi yi;
Omi nsun ni aginju,
Manna nt’ọrun wa fun wọn;
Nwọn nlọ lat’ ipa de ‘pa,
Titi nwọn fi yọ si Ọ;
Nwọn si wolẹ l’ẹsẹ Rẹ,
T’ o mu wọn là ewu já. - mf Baba, jẹ ki njère bẹ,
cr Ṣ’amọna mi laiye yi;
F’ ore-ọfẹ pa mi mọ.
Fun mi l’àye lọdọ Rẹ:
Iwọ l’ Orùn at’ Asà,
Tọ́ ọkàn ìṣina mi;
Iwọ l’ Orisun ore,
Rọ̀ òjo rẹ̀ sori mi.