Orin 234
Jesu, wá sarin wa
Jesus, stand among us
- mf Jesu, wá sarin wa,
L’ agbar’ ajinde;
Jẹ k’isìn wa nihin
Jẹ ìsin ọ̀wọ̀. - mp Mi Ẹmi Mimọ Rẹ,
Sinu ọkàn wa;
cr Mu ‘foiya at’ aro
Kuro l’ọkàn wa. - f Bi a ti nyara lọ,
Lọna àjo wa;
K’a ma ṣọna f’orọ̀
T’ ọj’ aiyeraiye. Amin.