Orin 228
Halleluya, Halleluya
Alleluia, alleluia!
- f Halleluya, Halleluya,
Ẹ gbe ohun ayọ ga,
Ẹ kọ orin inudidun,
K’ẹ si yiǹ Ọlọrun wa!
p Ẹnit’a kàn m’agbelebu,
T’o jiya fun ẹṣẹ wa;
ff Jesu Kristi Ọba ogo
Jinde kuro n’nu oku. - f Irin idabu ṣẹ́ kuro,
Kristi ku o si tun yè,
O mu iye ati aiku
Wa l’orọ ajinde Rẹ̀.
Krist ti ṣẹgun, awa ṣẹgun
Nipa agbara nla Rẹ̀,
ff Awa o jinde pẹlu Rẹ̀,
A o ba wọ’nu Ogo. - mf Kristi jinde, akọbi ni
Ninu awọn t’o ti sùn
Awọn yi ni y’o ji dide,
Ni abọ Rẹ̀ ekeji;
Ikore ti wọn ti pọ́n tan,
Nwọn nreti Olukore,
Ẹniti y’o mu wọn kuro,
Ninu isa oku wọn. - mf Awa jinde pẹlu Kristi,
To nfun wa l’ohun gbogbo,
Ojò, ìrì, ati ogo
To ntàn jade loju Rẹ̀.
Oluwa, b’ a ti wá l’aiye,
Fà ọkàn wa sọdọ Rẹ,
cr K’ awọn angẹli ṣa wa jọ,
Ki nwọn kó wa d’ọdọ Rẹ. - ff Halleluya, Halleluya !
Ogo ni fun Ọlọrun;
Halleluya f’ Olugbala,
Ẹnit’ o ṣẹgun iku;
Halleluya f’ Ẹmi Mimọ,
Orisun ‘fẹ, ‘wa mimọ,
Halleluya, Halleluya,
F’ Ọlọrun Metalọkan. Amin.