Orin 223
“Kabọ̀, ọjọ rere,” l’ao ma wi titi
Welcome, happy morning, age to age shall say:
- f “Kabọ̀, ọjọ rere,” l’ao ma wi titi;
A ṣẹtẹ ‘ku loni, Ọrun di ti wa.
“Wọ Okú d’ alayè, Ọba tit’ aiye !
Gbogb’ ẹda Rẹ Jesu, ni nwọn njuba Rẹ.
ff “Kabọ̀, ọjọ rere,” lao ma wi titi;
A ṣẹtẹ ‘ku loni, ọrun di ti wa. - mf Ẹlẹda, Oluwa, Ẹmi alayè !
Lat’ ọrun l’ o ti bojuwo ‘ṣina wa,
Ọm’ Ọlọrun papa ni ‘Wọ tilẹ ṣe,
K’ O ba lè gbà wa là, O di enia.
ff “Kabọ̀, ọjọ rere,” &c. - “Wọ Oluwa iye, O wa tọ ‘ku wò;
Lati f’ ipa Rẹ hàn, O sùn n’ iboji;
Wa, Ẹni Olotọ, si m’ ọ̀rọ Rẹ ṣẹ,
Ọjọ kẹta Rẹ de, jìnde Oluwa !
ff “Kabọ̀, ọjọ rere,” &c. - mf Tu igbekun silẹ, t’ Eṣu dè l’ẹwọn,
Awọn t’o si ṣubu, jọ gbe wọn dide;
F’ojurere Rẹ hàn, jẹ k’aiye riran,
Tun mu ‘mọlẹ wa de, ‘Wọ sá ni ‘mọlẹ;
ff “Kabọ̀, ọjọ rere,” lao ma wi titi;
A ṣẹtẹ ‘ku loni, ọrun di ti wa. Amin.