Orin 220
Lọ sọ fun gbogbo aiye
Go tell it to all the world
- f Lọ sọ fun gbogbo aiye,
cr Lọ tan ihin ayọ̀ yi;
Eti t’ o ba gbọ́, y’o ṣi,
Ọkàn t’ o ba gbọ́, y’o là - f Jesu Olugbala wa,
T’ a sin, fi boji silẹ̀;
Ọlọrun gba ẹbọ Rẹ̀,
Ẹbọ ẹ̀ṣẹ araiye. - mf O ji lati má kú mọ,
Akọbi awọn t’ o sùn;
Ẹniti o ba gba gbọ
Yio ye, b’ o tilẹ kú. - mf Angẹli ! ẹda ọrun,
f Ẹ ba araiye gberin;
Jesu Oludande ji,
Alafia titi lai. Amin.