Orin 22
Jesu, bukun wa k’a to lọ
O SAVIOUR, bless us ere we go
- mf Jesu, bukun wa k’a to lọ:
Gbìn ọ̀rọ Rẹ si aìya wa;
K’o sì mu k’ ifẹ gbigbona
Kun ọkàn ilọwọwọ wa;
cr Nigba ìye at’ iku wa,
p Jesu, jare, se ‘mọlẹ wa. - mp Ilẹ ti ṣu, orùn ti wọ̀;
‘Wọ sì ti ṣìro ìwa wa;
Diẹ n’ iṣẹgun wa loni
Iṣubu wa l’o papọju;
Nigba ìye ati, &c. - mf Jesu, dariji wa: fun wa
L’ ayọ, ati ẹ̀ru mimọ,
At’ ọkàn ti kò l’ abàwọn
K’a ba le jọ Ọ l’ajọtan:
Nigba ìye ati, &c. - Lala dùn, ‘tor’ Iwọ ṣe ri;
Aniyàn fẹ́rẹ, O ṣe ri;
Mà jẹ k’a gbọ t’ ara nikan
K’a má bọ sinu idẹwo.
Nigba ìye ati, &c. - mp A mbẹ Ọ f’awon alaini,
F’ẹlẹṣẹ̀ at’ awọn t’a fẹ;
Jẹ ki anu Rẹ mu wa yọ̀,
‘Wọ Jesu, l’ ohun gbogbo wa
Nigba ìye ati, &c. - mf Jesu, bukun wa, - ilẹ su:
Tikalarẹ wà ba wa gbe:
Angẹl’ rere nṣọ ile wa;
A tun f’ ọjọ kan sunmọ Ọ.
Nigba ìye ati, &c. Amin.