Orin 209
Ifẹ lo to bayi!
O perfect life of love!
- mp Ifẹ lo to bayi!
Ohun gbogbo pari,
O ti pari gbogbo iṣẹ
T’o tori rẹ̀ w’aiye. - Ohun ti Baba fẹ,
Ni Jesu ti ṣe tan:
p Wahala ati ìyà Rẹ̀
cr Mu Iwe Mimọ ṣẹ; - Kò s’ irora wa kan,
Ti Jesu ko jẹ rì;
Gbogbo ẹ̀dun at’ aniyan,
L’ ọkàn Rẹ̀ si ti mọ̀. - L’ ori t’a f’ẹgun dé,
At’ ọkàn Rẹ̀ mimọ,
L’ a kó gbogbo ẹṣẹ wa le,
K’ O ba le wò wa san. - p Ifẹ lo mu k’O kú
Fun emi otoṣi;
cr ‘Wọ Etutu f’ẹṣẹ̀ gbogbo,
Mo f’igbagbọ rọ̀ mọ. - mf Nigba aini gbogbo,
Ati n’itẹ ‘dajọ,
cr Jesu, ododo Rẹ nikan,
Ni igbẹkẹle mi. - mf Jọ, ṣiṣẹ ninu mi,
Bi O ti ṣe fun mi,
cr Si jẹ ki ifẹ mi si Ọ,
Ma fi ore Rẹ hàn. Amin.