Orin 20
‘Wọ Imọlẹ ! larin okun aiye
LEAD, kindly Light, amid the encircling gloom
- mp ‘Wọ Imọlẹ ! larin okun aiye
Ma sìn mi lọ.
Okunkun ṣù, mo si jina s’ ile;
Ma sìn mi lọ.
cr Tọ ‘ṣisẹ mi: ohun ẹhin ọla
Emi kò bere : ‘ṣisẹ̀ kan to fun mi. - p Nigbakan ri, emi ko bẹ Ọ, pe,
Ma sìn mi lọ.
Bẹni nkò fẹ Ọ; ṣugbọn nigbayi
Ma sìn mi lọ.
Afẹ aiye ni mo ti ntọ lẹhin;
Ṣugbọn Jesu, má ranti igbani. - mf Ipa Rẹ l’o ti ndi mi mu, y’o si
Ma sìn mi lọ.
Ninu ẹrẹ̀ ati yangi aiye,
Ma sìn mi lọ.
Titi em’ o fi ri awọn wọnni
Ti mo fẹ, ti nwọn ti f’ aiye silẹ. - K’o to d’igba na, lọna aiye yi
T’ iwọ ti rin,
Ma sìn mi lọ, Jesu Olugbala
S’ile Baba;
p Ki nle simi lẹhin ija aiye
Ninu imọle ti ko nipẹkun. Amin