Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 197

W’Olori Alufa Giga

Great High Priest, we see Thee stooping

Meter 8.7.8.7.8.7.8.7 Ijiya Jesu
  1. mp W’Olori Alufa Giga
    B’o ti gbe ẹ̀bẹ wa lọ;
    p L’ọgba, o f’ikedùn wolẹ̀,
    O f’ẹru dojubolẹ;
    Angẹli f’idamu duro
    Lati ri Ẹlẹda bẹ;
    cr Awa o ha wà l’ aigbọgbẹ,
    T’a mọ̀ pe tori wa ni?

  2. mf Kiki ẹjẹ Jesu nikan
    L’ o le yi ọkàn pada;
    On l’o le gbà wa n’nu ẹbi,
    On l’o ke m’ọkàn wa rò;
    Ofin at’ ìkilọ kò to,
    Nwọn kò si le nikan ṣe;
    cr Ero yi l’o m’ọkàn rò:
    Oluwa ku dipò mi !

  3. mf Jesu, gbogbo itunu wa,
    Lat’ ọ̀dọ Rẹ l’o ti nwá;
    cr Ifẹ, ‘gbagbọ, ‘reti, surù,
    Gbogbo rẹ̀ l’ẹjẹ Rẹ rà;
    f Lat’ inu ẹ̀kun Rẹ l’a ngba,
    A kò da ohun kan ni;
    Lọfẹ n’ Iwọ nfi wọn tọrẹ
    Fun awọn t’o ṣ’alaini. Amin.