Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 188

Ọlọrun, Baba mi, ‘Wọ npè

My God, my Father, dost Thou call

Meter L.M (8.8.8.8) Lenti, Isoji
  1. mp Ọlọrun, Baba mi, ‘Wọ npè
    Aṣako ọmọ Rẹ mọra?
    cr Iwọ o ha dariji mi?
    p Mo de, mo de, jọ gbà mi la.

  2. mp A! Jesu, Iwọ nrekọja
    Pẹlu ore at’ agbara?
    cr ‘Wọ kò ha ngbọ́ igbe mi bi?
    p Mo de, mo de, ṣanu fun mi.

  3. mp A! Ẹmi Mimọ, Iwọ ni?
    Ọrẹ ti mo ti ṣati pẹ!
    ‘Wọ ha mbẹ̀bẹ fun mi sibẹ?
    p Mo de, mo de, m’ailera le.

  4. cr Mo de, Oluwa, ifẹ Rẹ
    Ni o nrọ̀ mi t’o sì nfà mi:
    f Mo wolọ̀ lẹsẹ Rẹ, ki mmọ̀
    B’o ti dùn lati jẹ Tire. Amin.