Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 183

Gbogbo ẹjẹ ẹran

Not all the blood of beasts

Meter S.M (6.6.8.6) Lenti, Isoji
  1. mf Gbogbo ẹjẹ ẹran,
    Ti pẹpẹ awọn Ju;
    Kò lè f’ ọkàn l’ alafia,
    Kò lè wẹ eri nù.

  2. Kristi Ọd’agutan,
    p M’ẹ̀ṣẹ wa gbogbo lọ;
    Ẹbọ t’ o ni orukọ nla,
    T’ o ju ẹjẹ wọn lo.

  3. mf Mo f’ igbagbọ gb’ ọwọ
    Le ori Rẹ ọwọ́n;
    B’ ẹnt’ o ronupiwada,
    Mo jẹ́wọ ẹ̀ṣẹ mi.

  4. Ọkàn mi npadà wò
    p Ẹrù t’ Iwọ ti rù;
    Nigbati a kàn Ọ mọ ‘gi,
    Ẹṣẹ rẹ̀ wa nibẹ.

  5. f Awa nyọ̀ ni ‘gbagbọ,
    Bi egún ti kurò,
    ff Awa nyin Ọdọ-agutan,
    A nkọrin ifẹ rè. Amin.