Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 179

Baba alanu t’o fẹ wa

Father of mercy who loved us

Meter C.M (8.6.8.6) Lenti, Isoji
  1. mp Baba alanu t’o fẹ wa,
    Mo gb’ọkàn mi si Ọ;
    mf Ipá Rẹ t’ o pọ̀ l’ o gbà wa;
    Awa nkọrin si Ọ.

  2. f Tirẹ papa l’ awa fẹ ṣe,
    Gb’ ọkán wa fun ẹbọ;
    O da wa, o si tun wa bi,
    A f’ ara wa fun Ọ.

  3. Ẹmi Mimọ́, wá sọdọ mi,
    F’ ifẹ Oluwa hàn;
    Fun mi k’emi k’o lè ma rìn,
    N’ ifẹ Oluwa mi. Amin.