Orin 176
Ẹlẹṣẹ, ẹ yipada
Sinners, turn: why will you die?
- mp Ẹlẹṣẹ, ẹ yipada,
Eṣe ti ẹ o fi ku?
Ẹlẹda nyin ni mbere,
T’ o fẹ ki ẹ ba On gbe;
Ọràn nla ni o mbi nyin,
Iṣẹ ọwọ Rẹ̀ ni nyin.
cr A! enyin alailọpọ,
Eṣe t’ ẹ o kọ̀ ‘fẹ́ Rẹ? - p Ẹlẹṣẹ, ẹ yipada,
Eṣe ti ẹ o fi ku?
Olugbala ni mbere,
Ẹnit’ o ngb’ ẹmi nyin là;
Iku Rẹ̀ y’o jasan bi?
Ẹ o tun kan mọ ‘gi bi?
di Ẹni ‘rapada, eṣe
Ti ẹ o gàn ore Rẹ̀? - p Ẹlẹṣẹ, ẹ yipada,
Eṣe ti ẹ o fi ku?
Ẹmi mimọ ni mbere,
Ti nf’ọjọ gbogbo rọ̀ nyin;
Ẹ kì o ha gb’ore Rẹ̀?
Ẹ o kọ̀ iye sibẹ?
di A ti nwa nyin pẹ, eṣe
T’ẹ mbi Ọlọrun ninu? - cr Iyemeji ha nṣe nyin
Pe, ifẹ ni Ọlọrun,
Ẹ kì o ha gb’ ọrọ Re?
K’ ẹ gbà ileri Rẹ̀ gbọ?
p W’ Oluwa nyin lọdọ nyin,
pp Jesu nsun: w’omije Rẹ̀;
Ẹjẹ Rẹ̀ pẹlu nke, pe,
“Eṣe ti e o fi ku?” Amin.