Orin 173
Jesu, nigba’ danwò
In the hour of trial,
- mp Jesu, nigba’ danwò,
Gbadura fun mi;
K’emi má bà sẹ́ Ọ,
Ki nsi ṣako lọ:
cr ‘Gba mba nṣiyemeji,
K’o bojuwò mi;
L’ẹ̀ru tab’ isaju,
Ma mu mi ṣubu. - mp B’aiye ba si nfà mi,
Pẹlu adùn rẹ̀;
T’ ohun ‘ṣura aiye
Fẹ hàn mi l’emọ́;
Jọ mù Getsemane
di Wa s’ iranti mi,
pp Tabi irora Rẹ,
L’oke Kalfari. - mp B’o ba pọn mi l’oju,
Ninu ifẹ Rẹ;
Dà obilim Rẹ le,
Ori ẹbọ na:
Ki mf’ara mi fun Ọ.
Lori pẹpẹ Rẹ;
B’ ara kọ̀ ago na,
Igbagbọ y’o mu. - p ‘Gbà mo ba nrè boji,
Sinu ekuru;
cr T’ ogo ọrun si nkọ,
L’eti bèbe na;
mf Ngo gbẹkẹl’ otọ Rẹ,
N’ ijakadi ‘ku,
Oluwa, gb’ẹmi mi,
f S’ iye ailopin. Amin.