Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 166

Krist t’ agbelebu l’ orin wa

Christ Jesus our cross and our song

Meter C.M (8.6.8.6) Lenti, Ironupiwada
  1. mf Krist t’ agbelebu l’ orin wa,
    Ijinlẹ t’ awa nsọ;
    O j’ ẹgàn loju awọn Ju,
    Werè lọwọ Griki.

  2. Ṣugbọn ọkàn t’ Ọlọrun kọ́
    F’ ayọ̀ gba ọ̀rọ na;
    Nwọn ri ọgbọn, ipa, ifẹ,
    T’ o hàn n’Oluwa wọn.

  3. f Adùn orukọ Rẹ̀ yiyè
    Mu ‘sọji s’ọkàn wọn;
    Aigbagbọ l’ohun t’ o ba ni jẹ,
    p Si ẹbi at’ ikú.

  4. Lai j’Ọlọrun t’ o or’ ọfẹ ka
    Bi ọwara ojò;
    Lasan l’Apọllọs funrugbin,
    Paul si le gbìn lasan.