Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 153

Kò tọ k’ awọn mimọ́ bèru

It is not meet for Saints to fear

Meter C.M (8.6.8.6) Lenti, Ironupiwada
  1. mf Kò tọ k’ awọn mimọ́ bèru,
    Ki nwọn sọ ‘reti nu:
    ‘Gba nwọn kò reti ranwọ Rẹ̀,
    Olugbala y’o de.

  2. Nigbati Abram mu ọbọ,
    Ọlọrun ni, “Duro”;
    Agbo ti o wà lọhun ni,
    Y’o dipo ọmọ na”.

  3. p ‘Gba Jona rì sinu omi,
    Ko rò lati yọ mọ;
    Ṣugbọn Ọlọrun rán ẹja,
    T’ o gbe lọ s’ ebute.

  4. B’ iru ipa at’ ifẹ yi
    Ti pọ l’ ọ̀rọ Rẹ̀ to!
    Emi ba ma k’ aniyan mi,
    Le Oluwa lọwọ!

  5. f Ẹ duro de iranwọ Rẹ̀,
    B’ o tilẹ̀ pẹ, Duro,
    B’ ileri na tilẹ̀ falẹ̀,
    Ṣugbọn kò le pẹ de. Amn.