Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 151

Jesu mi, mu mi gb’ ohùn Rẹ

Jesus Christ make me hear Thy voice

Meter C.M (8.6.8.6) Lenti, Ironupiwada
  1. f Jesu mi, mu mi gb’ ohùn Rẹ,
    S’ọ̀rọ alafia;
    Gbogbo ipa mi
    Lati yin ore Rẹ̀.

  2. p Fi iyọnu pè mi l’ ọmọ,
    K’o si dariji mi;
    Ohùn na yio dunmọ mi,
    B’ iro orin ọrun.

  3. f Ibikibi t’ o tọ̀ mi si,
    L’emi o f’ ayọ lọ;
    Tayọtayọ l’emi o si
    Dapọ m’ awọn oku.

  4. f ‘Gba ẹ̀ru ẹbi ba kọja,
    Ẹru mi kò si mọ;
    Ọwọ t’ o fun ‘dariji ka,
    Y’o pín ade iyè. Amin.