Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 130

Gbọ orin ‘yin dida’ aiye

Hark, creation's alleluia

Meter 8.7.8.7.8.7.8.7 Ifihan, Mission
  1. Gbọ orin ‘yin dida’ aiye,
    T’ẹgbẹrun orilẹ nkọ,
    Orin didun bi t’angẹli,
    O ndún bi omi pupọ ---
    “Bukun, ogo, ipa, ‘gbala
    Fun Ọlọrun lor’itẹ,
    Baba, Ọmọ, Ẹmi, Mimọ
    Ọlọla ‘lainipẹkun.”

  2. Titi lọ, lat’orọ d’alẹ,
    Lor’olukuluku ‘lẹ,
    Lat’ ọpọlopọ enia’
    Ilu alawọ pupa,
    ‘Lawọ dudu t’ a da n’ ide ,
    Funfun ti o pọ niye,
    De ‘ le awọn Arabu.

  3. Lati ebutẹ otutu
    De ilẹ ti o morun,
    Lẹba okun pasifik,
    Lat’ọpọ aimoye ọkan
    Onigbagbọ alayọ ,
    Awọn to nsọna bibọ Rẹ,
    Nwọn fẹfẹ de sion na.

  4. Akojọ orilẹ-ede,
    Lat’inu ẹya ahọn,
    Gbọ, nwọn nkọrin iyin titi,
    Gbọ orin ologo ni,
    O b’ afonifoji mọlẹ,
    O si ndun lori oke,
    O ndun siwaju tit’o fi
    Kun ibugbe Ọlọrun.

  5. Gbọ, didun orin na dapọ
    Mọ orin awọn t’orun,
    Awọn t’o kọja n’ nu ‘ danwo
    Sinu isimi loke,
    Nwọn nfi duru kọ Hosanna,
    Ni’waju Ọlọrun wọn.

  6. “ Ogo fun Ẹnt’ o fẹ wa,
    T’ o wẹ wa n’nu ẹjẹ Rẹ,
    K’ọba, alufa, ma kọrin
    Si Baba, Ọlọrun wa.
    K’ enia mimọ on Angẹli,
    Kọ Alleluia titi :
    A ṣegun ọrun aradi :
    Olodumare jọba. “ Amin.