Orin 120
Oluwa y’o ti pẹ to
Lord how long will Thou tarry?
- mf Oluwa y’o ti pẹ to
Ti ‘Wọ o tun pada;
p Arẹ̀ fẹrẹ mu wa tan,
Bi a ti nwọna Rẹ;
Oluwa, y`o ti pẹ to
Ta o ma reti Rẹ?
Ọpọ ni kò gbagbọ mọ
Pe ‘Wọ o tun pada. - Oluwa y’o ti pẹ to
Ti ‘Wọ o kesi wa?
Ti awa, ti nreti Rẹ
Yio ri Ọ l’ayọ̀?
Ji, wundia ti o sùn,
Lọ kede bibọ Rẹ̀
Ki gbogbo awọn t’o sùn
Lè mọ̀ pe O mbọ wá. - f Dide, tan fitila rẹ,
Gbe ẹwù mimọ́ wọ̀,
Mura lati pade Rẹ̀,
‘Tori On fẹrẹ de.
Oluwa, y’o ti pẹ to
Ti ‘Wọ o tun pada?
Mà jẹ ki arẹ̀ mu wa
Tit’ a o fi ri Ọ. Amin.