Orin 118
Lat’ oke tutu Grinland
From Greenland’s icy mountains,
- mf Lat’ oke tutu Grinland,
Lati okun India,
Nib’ odo orùn Afrik,
Nṣan yanrin wura wọn:
Lat’ ọpọ odo gbani
Lati igbẹ ọpẹ
Nwọn npè wa k’a gba ‘lẹ wọn,
L’ẹwọ̀n iṣina wọn. - Afẹfẹ orùn didun,
Nfẹ jẹjẹ ni Seilon;
Bi ohun t’a nri dara
di Enia l’o buru:
mp Lasan lasan lỌlọrun
Nt’ ẹbùn Rẹ̀ gbogbo ka,
p Keferi, ni ‘fọju wọn.
Nwolẹ bọ okuta. - mp Njẹ awa ti a mòye
Nipa ọgbọn ọrun,
O tọ ka f’ imọlẹ du
Awọn t’ o wà l’ okùn?
ff Igbala, A, Igbala !
Fọnrere ayọ na
Titi gbogbo orilẹ
Yio mọ̀ Messia. - f Ẹfufu, mu ‘hin rẹ lọ,
Ati ẹnyin odo’
cr Titi, bi okun ogo
Y’o tàn yi aiye ka;
Tit’ Ọdagutan f’ a pa
Fun irapada wa
ff Yio pada wà jọba,
L’ alafia lailai. Amin.