Orin 110
Ẹnyin enia Ọlọrun
All ye the holy saints of God
- f Ẹnyin enia Ọlọrun,
Okunkun yi aiye ka;
Sọ ihin ayọ̀ ti Jesu
Ni gbogb’ orilẹ-ede;
Ihin ayọ̀, Ihin ayọ̀
Ti ‘toye Olugbala. - mf Má tiju Ihinrere Rẹ̀,
Agbara Ọlọrun ni.
N’ ilu t’a kò wasu Jesu,
Kede ‘dasilẹ f’ ondè;
Idasilẹ, Idasilẹ
Bi t’ awọn ọmọ Sion. - B’ aiye on Eṣu dìmọlu
S’ iṣẹ Olugbala wa,
Ja fun iṣẹ Rẹ̀, má fòya,
Màṣe bẹ̀ru enia.
Nwọn nṣe lasan, Nwọn nṣe lasan,
Iṣẹ Rẹ̀ kò le bajẹ. - p ‘Gbat’ ewu nla ba de si nyin,
Jesu y’o dabobo nyin;
Larin ọta at’alejo,
f Jesu y’o jẹ Ọrẹ́ nyin;
Itọju Rẹ̀, Itọju Rẹ̀
Y’ o pẹlu nyin tit’ opin. Amin.