Skip to content
Iwe Orin Mimo

Orin 102

B’ awọn ará igbanì

As with gladness men of old

Meter 7.7.7.7.7.7 Ifihan
  1. B’ awọn ará igbanì
    Ti f’ayọ̀ ri ‘ràwọ na;
    Bi nwọn ti f’inu didùn
    Tẹle ‘mọlẹ didan rẹ̀;
    Bẹ̀, Oluwa Olore
    Ni k’a mù wa d’ọdọ Rẹ.

  2. mf Bi nwọn ti fi ayọ lọ
    Si ibujẹ ẹran ná;
    Ti nwọn sì wolẹ nibẹ
    F’ Ẹni t’ọrun t’aiye mbọ;
    Gẹgẹ bẹ mo l’a má yọ̀
    Lati wá s’ itẹ anu.

  3. Bi nwọn ti mu ọrẹ wá
    Si ibujẹ ẹran na;
    Ba ni k’ awa ma f’ayọ̀
    Mimọ t’ẹṣẹ kò bajẹ
    Mu ‘ṣura wa gbogbo, wá
    Sọdọ Rẹ, Jesu Ọba.

  4. p Jesu mimọ, pa wa mọ,
    L’ọna toro l’ọjọjọ;
    cr ‘Gbat’ ohun aiye ba pin,
    M’ọkàn wa de ilu, ti
    f ‘Ràwọ kò nṣanmọ̀na mọ;
    ‘Biti nwọn nwò ogo Rẹ.

  5. Ni ‘lu ọrun mimọ na,
    Nwọn kò wá imọlẹ mọ;
    ‘Wọ l’Orùn rẹ̀ ti ki wọ;
    ‘Wọ l’ayọ̀ at’ ade rẹ̀;
    Nibẹ titi l’ao ma kọ
    Halleluya s’Ọba wa. Amin.