- f Ọlọrun Oluwa aiye
‘Wọ t’ o rán ‘rawọ̀ Rẹ,
Lati mu awọn amoye
M’ ọ̀na ibugbe Rẹ.
- ‘Gbawo’ ni ‘mọlẹ ọ̀rọ Rẹ
Y’o tàn yi ‘lu wa ka?
Ti aiya awọn ọba wa
Y’o fà si ọdọ Rẹ?
- T’ awọn ijoye wa gbogbo
Yio wá juba Rẹ;
Ti ohun ti a bi wọn bi
Y’o j’ asan loju wọn?
- p Ilẹ wa kun fun okunkun
Okun aiye-baiye,
Ohun inira ni fun wa,
Lati jade n’nu rè.
- f Ṣugbon Ọlọrun Oluwa,
Tàn ‘mọlẹ s’òkun wa,
K’ a lè ri wère ‘ṣina wa
K’ a le kọ̀ wọn silẹ̀.
- ff ‘Gbana ilu wa y’o logo
Y’o m’ọrẹ fun Ọ wá;
Ọrẹ t’ iṣe atinuwá,
At’ isìn otitọ. Amin.