Hymn 99: Almighty, Thou God of our peace

Oluwa alafia wa

  1. f Oluwa alafia wa
    L’o paṣẹ t’ ọdun yipo;
    Awa ọmọ Rẹ̀ wá dupẹ
    F’Ọdun titun t’a bẹrẹ.
    Yin Oluwa! Yin Oluwa!
    Ọba nla t’o da wa si.

  2. mf A dupẹ fun ipamọ wa
    Ni ọdun ti o kọja;
    A mbèbe iranlọwọ Rẹ
    Fun gbogbo wa lọdun yi.
    Jẹ k’ Ijọ wa, Je k’Ijọ wa
    Ma dagba ninu Kristi.

  3. f K’ agba k’o mura lati sin
    Lọkàn kan ni ọdun yi;
    K’ awọn ọmọe k’o mura
    Lati ṣafẹri Jesu.
    K’ alafia, K’ alafia
    K’ o ṣe ade ọdun yi.

  4. f K’Ẹmi Mimọ lat’ oke wá
    Bà le wa ni ọun yi;
    Ki Alufa at’ Olukọ
    Pẹlu gbogbo Ijọ wa
    Mura giri, Mura giri
    Lati jọsin f’Oluwa. Amin.