mf Ọdun miran ti kọja Wàwa l’akoko na lọ Ninu eyi t’a wà yi p Yio ṣ’ arimọ ọpọ Anu l’ o fi dá wa si, A ha lò ànu na bi? K’ a bi ‘ra wa ba ṣe tan? B’ a o pé wa l’ ọdun- ni
f Aiye bi ibi ija, Ẹgbẹgbẹrun l’ o nṣubu; mp Ọfa iku t’ o si nfò, A lè ran s’emi b’ iwọ; Nigb’a nwasu t’ a si ngbọ́, Oluwa jẹ k’a ṣarò P’ aiyeraiye sunmọle A nduro l’eti bèbe.
f B’a gba wa lọwọ ẹ̀ṣẹ Nipa ore-ọfẹ Rẹ, Njẹ ‘ma bọ̀ n ipè o jẹ, K’ a le lọ, k’ a r’ oju Rẹ: F’ enia Rẹ l’ aiye yi K’ anu wà l’ ọdun titun; Ọdun t’ o l’ ayọ ju yi, L’ eyi t’ o mú wọn de ‘le. Amin.