mf Baba ki m’ yà ọdun yi Si mimọ fun Ọ, N’ ipokipo ti o wù Ti O fẹ ki nwà: p Bi ‘banujẹ on ‘rora, Nkò gbọdọ kọmnu; Eyi ṣa l’adura mi “Ogo f’Okọ Rẹ.”
mf Ọm’ọwọ ha le paṣẹ ‘Biti on y’o gbe? Baba ‘fẹ ha le dù ni L’ẹbun rere bi? ‘Jojumọ n’Iwọ nfun wa Ju bi o ti tọ́, O kò dú wa l’ohun kan T’y’o yin Ọ l’ogo.
Ninu anu, l’Iwọ ba Fun mi li ayọ, cr B’alafia on ‘rọra Ba ’oju mi dán; f Gba ọkàn mi ba nkọrin, Jẹ k’o ma yìn Ọ, Ohun t’ọla ba mu wa. Ogo f’Okọ Rẹ.
p B’ O mu ‘pọnju wa ba mi, T’ọna mi ṣokun, T’ere mi di àdánù. Ti ile mi kan; cr Jẹ ki nranti bi Jesu Ṣe d’Eni ogo, Ki ngbadura n’nu ‘pọnju, “Ogo f’Okọ Rẹ”. Amin.