- mf Ọlọrun at’ ireti mi
Ọrọ Rẹ l’onjẹ mi,
Ọwọ Rẹ gbe mi ro l’ewe
Ati l’ ọdọmọde.
- Sibẹ mo nrohun iyanu
T’ O nṣe ni ọdọdun;
Mo fi ọjọ mi ti o kù
S’ iṣọ Tirẹ nikan.
- Mà kọ̀ mi, nigba ‘gbara yẹ̀,
Ti ewú ba bò mi,
ff Ki ogo Rẹ ràn yi mi ká
p Nigbati mo ba kú. Amin.