- mf B’ orùn l’aiduro ti rìn,
La ọdun ti o lọ já.
Bẹ l’ọpọ ti d’ opin wọn
A kì o si ri wọn mọ́.
- A sọ wọn l’ ojo lailai,
Tiwọn parí li aiye;
Awa duro diẹ̀ na,
Y’ o ti pẹ to, a kò mọ̀.
- f Gb’ ọpẹ f’ anu t’ o kọja,
p Tun dari ẹ̀ṣẹ ji wa;
Kọ wa b’ a ti wà, k’a má
Ṣe ‘ranti aiye ti mbọ̀.
- f Bukun f’ewe at’ agbà,
F’ ifẹ Oluwa kun wa;
‘Gba ọjọ aiye wa pin
K’ a gbe ọdọ Rẹ l’okè. Amin.