mf Oluwa at’ igbala wa, Amọna at’ agbara wa, L’ o kó wa jọ l’alẹ oni, Jẹ k’a gbe Ebeneser ro; Ọdun t’a ti là kọja yi, Ni on f’ ore Rẹ̀ de l’ ade, Ọtun l’ anu Rẹ̀ l’ owurọ; Njẹ ki ọpẹ wa ma po si!
mf Jesu t’ o joko lor’ itẹ, L’ a fi Halleluya wa fun; Nitori Rẹ̀ nikaṣoṣo L’ a da wa si lati kọrin; Ràn wa lọwọ lati kanu Ẹṣẹ ọdun t’ o ti kọja; Fun ni k’ a lo eyi ti mbọ, S’ iyìn Rẹ, ju ọdun t’ o lọ. Amin.