- f Ọlọrun, t’ ọdún t’ o kọja
Iret’ eyi ti mbọ̀;
Ib’ isadi wa ni ìji
At’ ile wa lailai.
- mp Labẹ ojiji itẹ Rẹ
L’ awọn enia Rẹ ngbe!
f Tito l’ apa Rẹ nikanṣo,
Abo wa si daju.
- mf K’ awọn oke k’ o to duro,
Tabi k’a to d’ aiye,
f Lailai Iwọ ni Ọlọrun
Abo wa si daju.
- Ẹgbẹrun ṣdun loju Rẹ,
Bi alẹ kan l’o ri;
B’ iṣọ kan l’afẹmọjumọ,
Ki orun k’o to là.
- Ọjọ wa, bi odò ṣiṣàn,
Ọpọ l’ o si ngbé lọ;
Nwọn nlọ, nwọn di ẹni ‘gbagbe,
Bi alá ti a nrọ.
- Ọlọrun t’ ọdun t’o kọja
Iret’ eyi ti mbọ̀,
Ma ṣ’ abo wa ‘gba ‘yọnu de
At’ ile wa lailai. Amin.