- mf Ọjọ ati akoko nlọ
Nwọn nsún wa s’ eti ‘boji;
p Awa fẹrẹ dubulẹ na,
Ninu ihò ‘busun wa.
- mf Jesu, ‘wọ Olurapada
Ji ọkàn t’ o ku s’ẹ̀ṣẹ;
cr Ji gbogbo ọkan ti ntogbe,
Lati yàn ipa iyè.
- mp Bi akoko ti nsunmọle,
Jẹ k’ a rò ‘bi to a nlọ;
Bi lati r’ayọ̀ ailopin,
pp Tabi egbé ailopin.
- mf Aiye wa nlọ!
pp Ikú de tan.
mf Jesu, ṣọ́ wa
pp Tit’ O fi de.
K’ a ba Ọ gbe
p K’ a ba Ọ kú,
f K’ a ba Ọ jọba titi lailai.
- mp Aiye wa nkọja b’ojiji
O si nfò lọ bi ‘kuku;
cr Fun gbogbo ọun t’o kọja
Dariji wa, mu wa gbọn.
- mf Kọ wa lati kà ọjọ wa,
Lati ba ẹ̀ṣẹ wa jà;
K’ a má ṣarẹ̀, k’ a má togbe
Tit’ a o fi ri ‘simi.
- f Gbogbo wa fẹrẹ̀ duro na
Niwaju itẹ ‘dajọ;
ff Jesu ‘wọ t’o ṣẹgun iku
Fi wa s’apa ọtun Rẹ.
- mf Aiye wa nlọ!
pp Ikú de tan:
Olugbala!
mf Jọ pa wa mọ.
K’a ba Ọ gbe,
pp K’ a ba Ọ kú,
f K’ a ba Ọ jọba titi lailai. Amin