f Apata aiyeraiye, Ẹnit’ o mbẹ̀ lailai, Nigbàkugba t’ìjì njà, p ‘Wọ ‘bugbe alafia; Ṣaju didá aiye yi, Iwọ mbẹ; bakanna Tit’ aiye ainipẹkun, Aiyeraye ni ‘Wọ.
p Ọj’ ọdun wa ri b’oji T’o hàn l’ori oke; Bi koriko ipado, pp T’o rú ti o si ku: Bi alá; tabi b’itàn, T’enikan nyara pa: p Ogo ti kò ni si mọ, Ohun t’o gbó tan ni.
f ‘Wọ ẹniti ki togbe, ‘Mọlẹ enit’ itàn; Kọ́ wa bi a o ti kà Ọjọ wa k’o to tán; Jẹ k’anu Rẹ bà le wa, K’Ore Rẹ pọ̀ fun wa; Si jẹ k’ Ẹmi Mimọ Rẹ, Mọlẹ si ọkàn wa.
mf Jesu, f’ẹwà at’ ore, Dé ‘gbagbọ wa l’ade; Tit’ ao fi ri Ọ gbangba, Ninu ‘mọlẹ lailai; Ayọ̀ t’ẹnu kò le sọ, Orisun akunya, Alafia ailopin, Okun ailebute. Amin.