- f Jesu, Orùn ododo,
Iwọ imọlẹ ifẹ;
Gbat’ imọlẹ owurọ
Ba nt’ ìla orùn tàn wá,
Tanmọle ododo Rẹ
Yi wa ka.
- mp Gẹgẹ bi ìri ti nsẹ̀
Sori eweko gbogbo,
K’ Ẹmi ore-ọfẹ Rẹ
Sọ ọkàn wa di ọtun;
Rọ òjo ibukun Rẹ
p Sori wa.
- mf B’imọlẹ orùn ti nràn,
K’ imọlẹ ifẹ Tirẹ,
Sì ma gbona l’ọkàn wa;
K’o si mu wa l’ara yà,
K’a le ma f’ayọ̀ sìn Ọ
L’aiye wa.
- Amọna, Ireti wa,
Ma fi wa silẹ titi;
Fi wa sabẹ iṣọ Rẹ
Titi opin ẹmi wa,
Sin wa là àjo wa ja
S’ile wa.
- Pa wa mọ n’nu ifẹ Rẹ
Lọjọ aiye wa gbogbo,
Sì mu wa bori iku,
Mu wa de ‘lẹ ayọ̀ na,
cr K’a le b’awọn mimọ gba
p Isimi. Amin.