- mf Igba mi mbẹ li ọwọ Rẹ,
A fẹ k’ o wà nibẹ;
A f’ ara wa at’ ọrẹ́ wa
Si abẹ iṣọ Re.
- Igba mi mbẹ li ọwọ Re,
Awa o ṣe bẹ̀ru?
p Baba kì y’o jẹ k’ ọmọ Rẹ̀
Sọkun li ainidi.
- Igba mi mbẹ li ọwọ Rẹ,
‘Wọ l’ a o gbẹkẹle;
Tit’ a o fi’ aiye òṣi ‘lẹ̀
T’ a o si r’ ogo Rẹ.
- mf Igba mi mbẹ li ọwọ Re,
Jesu t’ agbelebu;
p Ọwọ na t’ ẹṣẹ mi dalu,
cr Wa di alabo mi.
- f Igba mi mbẹ li ọwọ Rẹ;
Ngo ma simi le Ọ,
Lẹhin iku, l’ ọw’ ọtun Rẹ,
L’ em’ o wà titi lai. Amin.