mp Lẹhin ọdun diẹ, Lẹhin igba diẹ, di A o ko wa jọ pẹl’ awọn p Ti o sùn n’ ibojì. cr Oluwa, mu mi yẹẹ Fun ọjọ nlanla na! Jọ, wẹ̀ mi ninu ẹ̀jẹ Rẹ, p Sì ko ẹ̀sẹ mi lọ.
mp Lẹhìn ọjọ diẹ laiye buburu yi, di A o de ‘b’ orùn kò si mọ; Ilẹ daradara. cr Oluwa, mu mi yẹẹ Fun ọjọ nlanla na! &c.
mp Lẹhìn ìgbi diẹ L’ebute lile yi, di A o de ‘b’ ìji kò si mọ, T’ okun ki bù soke. cr Oluwa, mu mi yẹẹ Fun ọjọ nlanla na! &c.
mp Lẹhìn ‘yọnu diẹ Lẹhìn ‘pinya diẹ, Lẹhin ẹkun ati arò, A kì o sọkun mọ. cr Oluwa, mu mi yẹẹ Fun ọjọ nlanla na!
mf Ọjọ ‘simi diẹ L’a ni tun ri laiye; mp A o de ibi isimi f Ti kì o pin lailai. cr Oluwa, mu mi yẹẹ Fun ọjọ nlanla na!
f Ọjọ diẹ l’ o kù, On o tun pada wà; mp f Ẹnit’ o ku ‘ awa le yè, K’a ba le ba jọba. Mf Oluwa, mu mi yẹẹ Fun ọjọ nlanla na! &c. Amin.