f Wà ẹnyin olotọ, L’ayọ at’ iṣẹgun, Wá kalọ, wa kalo si Bẹtlehẹm, Wà kalọ wò o! Ọba awọn Angẹl! p Ẹ wá kalọ jubà Rẹ̀, Ẹ wá kalọ jubà Rẹ̀, f Ẹ wá k’a lọ jubà Kristi Oluwa.
Olodumare ni, Imọlẹ Ododo, p Kò ai korira inu Wundia; f Ọlọrun papa ni, Ti a bi, t’ a kò dá: p Ẹ wá kalọ jubà Rẹ̀, &c.
f Angẹli, ẹ kọrin, Kọrin itoye rẹ̀; Ki gbogbo ẹda ọrun sì gberin: Ogo f’Ọlọrun L’ oke ọrun lọ́hun: p Ẹ wá kalọ jubà Rẹ̀, &c,
f Nitotọ, a wolẹ F’Ọba t’ a bi loni; Jesu Iwọ li awa nfi ogo fun: ‘Wọ ọmọ Baba, T’o gbé ara wa wọ̀! p Ẹ wá kalọ jubà Rẹ̀, Ẹ wá kalọ jubà Rẹ̀, cr Ẹ wá kalọ juba Kristi Oluwa. Amin.