f Ayọ̀ kun ọkàn wa loni A bi Ọmọ Ọba; Ọpọ awọn ogun ọrun, Nsọ ìbí Rẹ̀ loni ; ff Ẹ yọ̀, Ọlọrun d’enia, O wá joko l’ aiye ; Orukọ wo l’ o dun to yi – Emmaunel.
mp A wolẹ n’ ibujẹ ẹran, N’ iyanu l’a jọsìn: cr Ibukun kan kò ta ‘ yi yọ, Kò s’ayọ̀ bi eyi ff Ẹ yọ̀, Ọlọrun, &c.
mf Aiye kò n’ adùn fun wa mọ, ‘Gbati a ba nwò Ọ; L’ọwọ Wundia iya Rẹ, ‘Wọ Ọmọ Iyanu. ff Ẹ yọ̀, Ọlọrun, &c.
f Imọlẹ Lat’ inu ‘ Mọlẹ̀, Tan ‘mọle s’ okùn wa; K’ a le ma fi ìsin mimọ́, Ṣe ‘ranti ọjọ Rẹ. ff Ẹ yọ̀, Ọlọrun d’ enia, O wà joko l’ aiye; Orukọ wo l’ o dun to yi— Emmaunel. Amin.