- f ‘Gba Jehofah da aiye;
cr ‘Gbat’ o sọrọ̀ t’ o si ṣẹ,
Awọn Angẹli nkọrin
ff Halleluya gb’ ọrun kan.
- mf Orin ‘yìn l’ a kọ l’ orọ̀
Gbat’ a bi Olugbala;
cr Orin ‘yìn ni a si kọ
Nigbat’ o digbekùn lọ.
- p ‘Gbat’ aiye y’o kọja lọ
Iyìn o gb’ ọjọ na kan;
‘Gbat’ a o d’ aiye titun,
Orin iyin l’ a o kọ.
- Awa o ba dakẹ bi
Titi jọba na o de?
Bẹkọ ! Ijọ o ma kọ
Orin mimọ́ at’ iyìn.
- Enia mimọ́ l’ aiye,
Nf’ ayọ̀ kọrin iyìn na;
Nipa ‘gbagbọ ni nwọn nkọ,
Bi nwọn o ti kọ l’ oke.
- p Nigba ẹmí o ba pin
Orin ni o ṣẹgun ‘ku;
f Ninu ayọ̀ ailopin
Nwọn o ma kọrin titi. Amin