Hymn 81: Hark! The herald angels sing

Gbo eda orun nkorin

  1. f Gbọ́ ẹda ọrun nkọrin,
    “Ogo fun Ọba t’a bi.”
    p “Alafia laiye yi”
    cr Ọlọrun ba wa làja.
    f Gbogbo ẹda, nde layọ̀,
    Dapọ mọ hìhó ọrun;
    W’ Alade alafia !
    Wo Orùn ododo de.

  2. mp O bọ ‘go Rẹ̀ sapakan,
    cr A bi k’ enia má ku,
    A bi k’ o gb’ enia ró,
    A bi k’ o le tun wa bi.
    mf Wá, ireti enia,
    Ṣe ile Rẹ ninu wa;
    N’de, Iru Ọmọbirin,
    Bori Eṣu ninu wa.

  3. cr Pa aworan Adam run,
    F’ aworan Rẹ s’ ipò rẹ̀;
    Jọ, maṣai f’ Ẹmi Rẹ kún
    Ọkàn gbogb’ onigbagbọ,
    ff “Ogo fun Ọba t’ a bi”
    Jẹ ki gbogbo wa gberin,
    f “Alafia laiye yi,”
    Ọlọrun ba wa làja. Amin.