- Wo ! gbogbo ilẹ okunkun,
Wo ! ọkàn mi, duro jẹ;
Gbogbo ileri ni o nsọ
T’ ọjọ ayọ t’ o l’ ogo;
Ọjọ ayọ ! Ọjọ ayọ !
K’ owurọ rẹ yara de !
- Ki India on Afrika,
K’ alaigbede gbogbo ri
Iṣẹgun nla t’ o logo ni,
T’ ori oke Kalfari;
K’ ihinrere, K’ ihinrere
Tan lat’ ilu de ilu.
- Ijọba t’ o wà l’ okunkun,
Jesu, tàn ‘mọlẹ fun wọn.
Lat’ ila-orùn de ‘wọ rẹ̀,
K’ imọlẹ lé okùn lọ;
K’ irapada, K’ irapada,
Ti a gbà l’ ọfẹ bori.
- Ma tàn lọ, ‘wọ ihinrere,
Ma ṣẹgun lọ, má duro;
K’ ijọba rẹ aiyeraiye
Ma bi sì, k’ o si ma rè;
Olugbala, Olugbala,
Wá jọba gbogbo aiye. Amin.