- Imolẹ̀ orọ̀ didun yi
Jí mi nin’ orun mi;
Baba, ífẹ Tirẹ nikan
L’ o pa ọmọ Rẹ mọ.
- Ni gbogbo oni, mo bẹ̀ Ọ,
Ma ṣe Oluṣọ mi;
Darijì mi, Jesu mimọ
Ki ‘m jẹ Tirẹ loni.
- Wà ṣe ‘bugbe Rẹ ninu mi,
Ẹmi ore-ọfẹ!
Sọ mi di mimọ laiye yi,
K’ emi le r’oju Rẹ. Amin.