- f Onigbagbọ, ẹ bu s’ayọ̀,
Ọjọ nla l’eyi fun wa;
Ẹ gbọ bi awọn Angẹli
Ti nf’ ogo fun Ọlọfun;
Alafia, Alafia
Ni fun gbogbo enia.
- ff Ki gbogbo aiye ho f’ayọ̀,
K’ a f’ ogo fun Ọlọrun,
Ọmọ bibi Rẹ̀ l’ o fun wa
mf T’ a bi ninu Wundia;
Ẹn’ Iyanu, Ẹn’ Iyanu
Ni Ọmọ t’a bi loni.
- Ninu gbogbo rudurudu,
On ibi t’ o kun aiye,
Ninu idamu nla ẹ̀ṣẹ
L’ Ọm’Ọlọrun wà gbà wa;
Olugbimọ, Olugbimọ,
Alade Alafia.
- f Ọlọrun Olodumare
L’ a bi, bi ọmọ titun;
Baba! Ení aiyeraiye
L’ o di alakoso wa:
ff E bú s’ayọ, Ẹ bu’ s’ ayò,
Ọmọ Dafidi jọba.
- p O wà gbà wa lọwọ ẹṣẹ,
O wà d’ onigbọwọ wa
Lati fọ itẹgun Eṣu
A ṣe ni Ọba ogo;
f Ẹ kù ayọ̀, Ẹ kù ayọ̀,
A gbà wa lọwọ ikú. Amin.