f Ẹnyin Angẹl l’ọrun ogo, To yi gbogbo aiye ka; Ẹ ti kọrin dida aiye, Ẹ sọ t’ ibi Messia; Ẹ wà jọsìn, E wà jọsìn, Fun Kristi Ọba titun.
mf Ẹnyin Olusọ-agutan, Ti nṣọ ẹran nyin loru, cr Emmanueli wa ti de, Irawọ ọmọ na ntàn; f Ẹ wà jọsìn, &c.
mf Onigbagbọ ti ntẹriba, Ni ‘bẹru at’ ireti L’ ojiji l’ Oluwa o de Ti yio mu nyin re ‘le, f Ẹ wà jọsìn, &c.
mp Ẹlẹṣẹ ‘wọ alaironu p Ẹlẹbi ati ègbé Ododo Ọlọrun duro, Anu npe ọ, pa ‘wà dà; f Sa wà jọsìn, &c.
mf Gbogbo ẹda ẹ fò f’ ayọ̀, p Jesu Olugbala de, mf Anfani miran kò si mọ́ B’ eyi ba fò nyin kọja; f Njẹ, ẹ wà jọsìn, Njẹ, ẹ wà jọsìn, Sin Kristi Ọba Ogo. Amin.