f Ji, ‘wọ, Kristian, k’ o ki orọ ayọ Ti a bi Olugbala araiye; Dide, k’ o kọrin ifẹ Ọlọrun, T’ awọn Angẹli nkọ n’ ijọ kini. Lat’ ọdọ wọn n’ ihin na ti bẹrẹ; Ihin Ọm’ Ọlọrun t’ a bi s’aiye.
f ‘Gbana l’ a ran akede Angẹli, T’ o sọ f’ awọn Oluṣagutan, pe, “Mo mu ‘hin rere Olugbala wá, T’ a bi fun nyin ati gbogbo aiye, Ọlọrun mu ‘leri Rẹ ṣẹ loni, A bi Olugbala Krist Oluwa.”
mf Bi akede Angẹl na ti sọ tan, Ọpọlọpọ ogun ọrun sì de; Nwọn nkọrin ayọ̀ t’ eti kò gbọ́ ri, Ọrun si ho fun yìn Ọlọrun pe, “Ogo ni f’Ọlọrun l’ oke ọrun, Alafia at’ ifẹ s’ enia.”
mf O yẹ k’ awa k’ o ma ró l’ọkàn wa, Ife nla t’ Ọlọrun ni s’ araiye; K’ a si ro t’ ọmọ na r’ a bi loni, T’ o wá jiya oro agbelebu. Ki awa si tẹle ilana Rẹ̀, Titi a o fi de ibugbe l’ okè.
f Nigbana ‘gba ba de ọrun lọhun, A o kọrin ayọ̀ t’ irapada; Ogo enit’ a bì fun wa loni, Y`o ma ràn yi wa ka titi lailai A o ma lọrin ifẹ Rẹ̀ titi, Ọba Angẹli, Ọba enia. Amin.