Hymn 74: Lift up your heads, eternal gates

Gbe ori nyin s’ oke, enyin

  1. f Gbe ori nyin s’ oke, ẹnyin
    ‘Lẹkun aiyeraiye:
    Gbà Ọba ogo: wo, o mbọ
    Pẹl’ ogun ọrun rẹ̀.
    mp Ta l’Ọba Ogo yi? Tani?
    cr Oluwa t’ o n’ ipa
    f T’ o l’ agbara l’or’ ọta Rè,
    Aṣẹgun, Alade.

  2. mf Gbe ori nyin s’ okè , ẹnyin
    Ilẹkun: lati gbà
    f Ọba Ogo: ẹ wo, o mbọ̀
    Pẹl’ ogun didan Rẹ̀.
    mp Ta l’Ọba Ogo yi? Tani?
    cr Oluwa t’ o n’ ipa,
    f L’ogo on nikan li Ọba,
    T’ a f’ ogo dé l’ ade. Amin.