- f Ọjọ dajọ, ọjọ ẹru!
Gbọ́ bi ipè ti ndún to!
O ju ẹ̀gbarun ará lọ
O si nmì gbogbo aiye.
p Bi ẹ̀sùn na
Y’ o ti damu ẹlẹṣẹ!
- mf Wò Onidajọ l’àwọ wa,
T’ o wọ ogo nla l’aṣọ
Gbogbo wọn ti nwo ọnà Rẹ̀,
‘Gbana ni nwọn o ma yọ̀.
p Olugbala,
Jẹwọ mi ni ijọ na.
- f Ni pipè Rẹ̀ okù o jí
Lat’ okun, ilẹ, s’ iye;
Gbogbo ipa aiye y’o mì,
Nwọn o salọ loju Re.
p Alaironu,
Yio ha ti ri fun ọ?
- Eṣu ti ntàn ọ nisiyi,
Iwo mà ṣe gbọ tirẹ̀,
‘Gbati ọ̀rọ yi kọja tan,
Y’o rì ọ ninu iná;
p Iwọ ronu
Ipò rẹ ninu ina!
- Labẹ ipọnju, at’ẹgan,
K’eyi gba ọ n’ iyanju;
Ọjọ Ọlorun mbọ tete,
‘Gbana ẹkùn y’o d’ ayọ,
f A o ṣẹgun
Gbati aiye ba gbina. Amin.