Hymn 71: Great God, what do I see and hear!

Olorun ! kini mo ri yi !

  1. f Ọlọrun! Kini mo ri yi!
    Opin de f’ ohun gbogbo!
    Onidajọ araiye yọ,
    O gunwa n’ itẹ ‘dajọ,
    ff Ipè dùn, iboji si tú
    Gbogbo awọn okù silẹ;
    p Mura, lọ ko, ọkàn mí.

  2. mf Okú ‘nu Krist y’o kọ́ jinde,
    Nigba ‘pe kẹhin ba dùn;
    Nwọn o lọ ko l’ awọsanma,
    Nwọn o fi ayọ yí ka;
    Ko s’ẹru ti y’o b’ ọkan wọn;
    Oju Rẹ̀ dà imọlẹ bo,
    Awọn ti o mura dé.

  3. p Ṣugbọn ẹlẹṣẹ t’ on t’ ẹ̀ru!
    Ni gbigbona ‘binu Rẹ̀,
    Nwọn o dide, nwọn o si ri,
    Pe, oṣé wọn kò bá mọ;
    pp Ọjọ ore-ọfẹ kọja;
    Nwọn ngbọ̀n niwaju ‘tẹ ‘dajọ,
    Awọn ti kò mura de.

  4. un Ọlọrun kini mo ri yi;
    Opin de f’ohun gbogbo!
    Onidajọ araiye yọ,
    O gunwà n’ itẹ ‘dajo.
    p L’ẹsẹ agbelebu, mo nwò
    ‘Gbat’ ohun gbogbo y’ o kọja;
    cr Bayi ni mo nmura de. Amin.