- mf Wo! Oluwa l’ awọ̀sanmà,
O mbọ l’ogo, l’ ọla Rẹ̀.
Ẹni t’ a pa tun ẹlẹṣẹ
Mbọ pẹlu Angeli Rẹ̀;
ff Halleluya!
Halleluya! Amin .
- Gbogbo ẹda, wá wò Jesu,
Aṣọ ogo l’ a wọ̀ fun;
p Awọn t’ o gan, awọn t’o pa,
T’ o nkan mọ agbelebu;
pp Nwọn o sọkun
Bi nwọn ba ri Oluwa.
- Erekuṣu, okun, oke,
Ọrun, aiye, a fò lọ
Awọn t’ o kọ a dà wọn rú,
Nigbati nwọn gbohun Rẹ̀,
pp Wá s’ idajọ
Wa s’ idajọ, wá kalọ!
- Irapada t’ a ti nreti,
O de pẹlu ogo nla;
Awọn ti a gàn pẹlu Rẹ̀
Yio pade Rẹ̀ loj’ ọrun!
ff Halleluya
Ọjọ Olugbala de. Amin.