- mf Wá s’adura orọ̀
Kunlẹ k’a gbadura:
f Adura ni ọpa Kristian,
Lati b’ Ọlọrun rìn.
- mf Lọsan, wolẹ̀ labẹ
Apat’ aiyeraiye;
p Itura ojiji Rẹ̀ dùn
Nigbat’ orun ba mù.
- mf Jẹ ki gbogbo ile
Wà gbadura l’ alẹ;
Ki ile wa di t’ Ọlọrun
di Ati ‘bode ọrun.
- p Nigbat’ o d’ ọganjọ,
Jẹ k’a wi l’ẹmi, pe
Mo sùn, ṣugbọn ọkàn mi ji
Lati ba Ọ ṣọnà. Amin.