- mf Ẹnyin t’o ngb’ oke ọrun,
mp Ẹ sọ ‘Ta l’Ọba Ogo’?
Ta l’ o ga julọ nibẹ?
T’ o si l’agbara gbogbo?
- Ọd’ Agutan nikan ni,
L’ o pe oyè na ni t’ On;
On l’o wà lori itẹ,
On si ni Ọba Ogo.
- Ihin nla! Jesu l’ Ọba,
On nikan l’ o sì jọba;
W’ ọdọ Rẹ̀ t’ ẹnyin t’ ọrẹ,
Ẹ wolẹ niwaju Rẹ̀.
- Jẹ k’ aiye k’o rẹrin Rẹ̀,
Je ki nwọn kọ̀ lati sìn,
Angẹl nyọ̀ l’ orukọ Rẹ̀,
Gbogbo ẹda ọrun nsìn.
- A yìn Ọ, ‘Wọ t’ Angel nsìn,
Ọd’ Agutan Ọlọrun,
Ma jọba titi lailai
Ọba yẹ Ọ, Oluwa. Amin.